Enquiries: +2348073528899, 09168692180 || support@fulfillmentict.com
1 C.M.S. 1. H.C. 2. L.M. (FE 19)
“Emi tikarami yoo ji ni kutukutu” -Ps. 108:2
1. JI, ọkan mi, ba orun ji
Mura si isẹ oojọ rẹ;
Mase ilọra, ji kutu,
K'o san gbese ẹbọ oorọ.
2. Ro gbogb' ọjọ t'o fi sofo;
Bẹrẹ si rere 'se loni;
Kiyes' irin rẹ laye yi;
K'o si mura d'ọjọ nla ni.
3. Gba ninu imọlẹ ọrun,
Si tan 'mọlẹ na f'ẹlomi,
Jẹ ki ogo Ọlọrun rẹ,
Han n'nu wa ati ise rẹ.
4. Ji, gbọn 'ra nu 'wọ ọkan mi
Yan ipo rẹ larin Angẹl,
Awọn ti wọn n kọrin iyin,
Ni gbogbo oru s'Ọba wa.
AMIN
2 C.M.S. 1 H.C. 2 L.M. (FE 19)
1. MO ji, mo ji, ogun ọrun,
K'emi l'agbara bi ti yin;
K'emi ba le lo ọjọ mi.
Fun iyin Olugbala mi.
2. Ogo fun Ẹni t'o sọ mi
To tu mi lara loju orun
Oluwa, ijọ mo ba ku
Ji mi s'iye ainipẹkun.
3. Oluwa mo tun ẹjẹ jẹ,
Tu ẹsẹ ka b'iri ọrọ;
Sọ akọronu mi oni
Si f’Ẹmi Rẹ kun inu mi.
4. Ọrọ at'ise mi oni,
Ki wọn le ri bi ẹkọ Rẹ;
K'emi si f'ipa mi gbogbo,
Sisẹ rere fun Ogo Rẹ.
AMIN
To get the complete hymn (full version), kindly click here now