Enquiries: +2348073528899, 09168692180 || support@fulfillmentict.com
ORIN 1
1. Maa wi, 'tori 'ranṣẹ Rẹ n gbọ,
Mo n duro de ọrọ Rẹ,
Mo fẹ gb' ohun iwosan Rẹ,
Jẹ k' emi gbọ Oluwa;
Mo tẹ 'ti silẹ Oluwa,
S' ohun t' O fẹ wi fun mi.
2. Maa wi, pe mi, Oluwa mi,
Jẹ ki n le mọ ohun Rẹ,
Maa wi, ki n yara tẹle Ọ,
Ki n sunmọ Ọ girigiri,
Nibiti O n tọ agbo Rẹ,
L' abẹ ibi itura.
3. Maa wi, yala l' ohun jẹjẹ,
Ma jẹ k' emi lọ l' aigbọ,
Maa wi, Oluwa, Iwọ mọ,
Gbogbo eero ọkan mi,
Iwọ mọ ohun ti mo n fẹ,
Sọ mi di ẹni 'bukun.
4. Maa wi, jẹ ki emi mura,
Bi mo ba ti gb' ohun Rẹ,
Pẹlu 'gbọran ati ayọ;
Ni ki n fi tẹ l' Ọrọ Rẹ,
Mo tẹ 'ti silẹ Oluwa,
Maa wi, Oluwa maa wi.
Amin.
ORIN 2
1. Mo fi gbogbo ọkan mi tan,
Ẹnit' O le gb' ẹmi mi la,
Abo n la ti ki 'yẹ laelae;
Ọrọ Rẹ daju.
EGBE:
"Em' ni Alfa, at' Omega,
Ipilẹṣẹ ati opin;
Ti O wa, t' O ti wa,
Ti O si n bọ wa,
Em' ni Alfa, at' Omega,
Ipilẹṣẹ ati opin,
Olodumare, Olodumare,"
L' Oluwa wi.
2. Ọkan mi n sọ pẹlu ayọ,
Ti ẹni ti n gbe inu mi,
If' ẹni ti n tẹ l' ọrọ Rẹ,
Lati mu duro.
3. Jehofa Ọlọrun gba mi,
Lọwọ 'yemeji at' ẹru,
Fi 'gbagbọ gbigbona fun mi,
K' ọkan mi duro.
Amin.
To get the complete hymn (full version), kindly click here now